ÌJÚBÀ ỌLỌRUN FUN ÌGBÉ AYÉ TÓ NÍTUMỌ̀ (BÀBÁ G.O. OLUTỌ́LÁ)
*ÌJÚBÀ ỌLỌRUN FUN ÌGBÉ AYÉ TÓ NÍTUMỌ̀ (BÀBÁ G.O. OLUTỌ́LÁ)*
********************************
Erin ti wó.
Àjànàkú ti sùn bí òké.
Ikú ti pabírí, abírí ti kú, abìrì ti rọ̀run alákeji.
Baba ti papòdà, Bàbá àwọn Bàbá ràjò àrèmabọ̀.
Ọ̀gá àwọn ọ̀gá dágbére fáyé.
Ọkọ Ọlánlrewájú Àpèkẹ́ re’lé ogbó.
Baba Bọlanle, Bàbá Ìbejì, Baba Àbẹ̀bí ti re’bi àwọn gbà á rè.
Daddy mi, ó dàárọ̀ Sà.
Ọ̀kanṣoṣo Àràbà tó tún d’ìrókò lójú gbogbo akọ igi, àwọn akọgi níjù ò rí nkankan ṣe si.
Bẹ́ẹ̀ni o, Ọlọrun lo dé, ó kọjá ọgbọ́n àtinùdá.
Hùnm… Ó tún di bẹ́ni bá njọni.
Gabriel Àkànní Ojúkan-ẹ̀pà,
Mọ̀tún Ọlọ́mọ̀ kẹ́ẹ́ jakọ ẹyẹ.
Ẹ̀ṣọ́’Kòyí’, Ọmọ agbọ̀n-iyùn.
Balógun àwọn jagunjagun inú ọgbà àjàrà Oluwa àwọn ọmọ ogun,
O ti wá, o rí, O ti jà, O ti ṣẹ́gun, O fidà rẹ lélẹ̀ lẹ́sẹ̀ Jesu Olùgbàlà, ìpàdé tún dọjọ́ àjínde, níbi àsè ìgbéyàwó àwọn ẹni mímọ́ pẹ̀lú Jesu Kristì Ọkọ’yàwó ọjọ náà.
Ọladele ọ̀mọ Olutọla, ó dìgbà kan ná.
Gbòngbò ìdílé Bàbá Àlùkò l’Ókè’Bodè, ó tún d’ojú àlá.
Baba *to match*.
Gbogbo aga tó wà nínú ìjọ yì ni Bàbá G.O fìdí bà láìkùkakankan.
Ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ọjọ́ ìsinmi ni Bàbá Olutọla.
Mẹ́mbà kíkún ni Bàbá.
Olùkọ́ àwọn ọmọ akẹ́kọ̀ọ́ ọjọ́ ìsinmi ni Bàbá.
Ọmọ ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ni Bàbá.
Ọmọ ẹgbẹ́ ajẹ́rí ni Bàbá.
Díákónì ni Bàbá Olutọla,
Alàgbà ni Bàbá.
Bàbá re Sẹmínárì.
Bàbá ṣe Wọ́kà nínu ọgbà Oluwa.
Bàbá tún gba kọ́là olùṣọ́ àgùtàn.
Bàbá di àlùfáà ijọ títí dé Àpostelì agbègbè.
Wòlíì ni Bàbá.
Ajihìnrere ni Bàbá,
Alábójútó àwon Ìpínlẹ̀ tó pọ ni Bàbá.
Akòwé Àyíkáa LAWNA ni Bàbá.
Bàbá tún di Alága Àyíkáa LAWNA.
Ní mẹ̀lọ-mẹ̀lọ, lẹ́ẹ̀kannáà, Ọládélé ọmọ Olútọ́lá d’ààrẹ fún Ìjọ Aposteli Nàá ní gbogbo ìbùdó àti ìletò àwọn ọmọ adáríhurun.
Bàbá Olutọla kàwé o.
Ọlọ́pọlọ pípé sì ni Bàbá.
Láti ilé-ìwé akọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ ní ìlú Òkè’Bodè, tó fi de aṣíwájú nínu àwọn ilé ẹ̀kọ́gíga lágbàáyé, (Harvard University) ti ìlú Amẹrikà.
Olùṣàkóso ìjọ tí a fiyọ̀ dùn ni Bàbá.
Olùfọkànsìn nítòótọ́ ni Bàbá. Nínú iṣẹ́ Olúwa pẹ̀lú iṣẹ́ ìhìnrere ní ṣíṣe, Ìránṣẹ́ Ọlọrun tààrà ni G.O. Olútọ́lá. Àkàṣù iyán tó jámọlórí ni Bàbá Olútọ́lá í ṣe.
Bàbá làkàkà, Ó se ìrànlọwọ fun ìtìleyìn ọ̀nà náà.
Òlùtọ́jú ilé pẹ̀lú àwọn ọmọ ni Bàbá.
Ní ti àpọnlé, Bàbá fi tẹ̀rín-tọyàyà yẹ́ ọmọdé sí, Ó tún bù lé tàgbà.
yàtọ sí tìgbàgbọ Òké-Oòyè, Bàbá ni Bàbá Olutọla now gbogbo Ọkùnrin ìjọ, tí gbogbo àwọn Obìnrin ìjọ sì di Mọmọ.
Nínú gbogbo iṣẹ́ tí Bàbá yàn láàyò pátápátá, òdù ni Bàbá jẹ́, kìí ṣàìmọ̀ fólóko.
Àgbẹ̀ Aládàánlá ni Bàbá.
Nínú iṣẹ́ ọ̀gbìn, ògúnná gbòngbò tí ndátọ lẹ́nu ìgbín ni Bàbá.
Amúnidára ni Bàbá.
Bàbá ṣiṣẹ́ nínú ọgbà, Ó jèrè iṣẹ́.
Ìlúmọ̀ọ́ká ni Bàbá nínú iṣẹ́ Olúwa
Ẹni à ndúró dè ni Bàbá, tó tùn fi Ararẹ̀ sábẹ́ ìṣàkoso àwọn Baba.
Olùgbàlejò pàtàkì ni Bàbá.
Bàbá sè, *Ó JINNÁ*.
Nítòótọ́ ni Bàbá dàgbà, Bàbá gbó, Bàbá pọ́n, kò sí bárúgbó ẹni ṣe wù kó d’ogbó tó, a kìí fẹ́ kó kú, ṣùgbọ́n ìbá ṣe páìíkú láyé, ará ìgbà’un dà?
Gbogbo ẹbí, ará, ọrẹ, àti gbogbo ìjọ Ọlọrun, nílé, lóko àti lẹ́yìn-odi ló nṣeledè ẹni wa rere tó lọ sinmi.
Erin ti wó o.
Àgùnfọn.
Erin ti gòkè àlọ̀ọ̀.
Níkẹ̀ẹ́agbẹ́ja Adésànyà ló fọwọ́ si ọ̀rọ̀ Ìjúbà náà.